Bí o bá fẹ́ẹ jẹ ànfààní àyọkúro owó orí oúnjẹ láti òkè òkun, èyíi ni àwọn ohun tí o gbọdọ̀ ní - BBC News Yorùbá (2024)

Bí o bá fẹ́ẹ jẹ ànfààní àyọkúro owó orí oúnjẹ láti òkè òkun, èyíi ni àwọn ohun tí o gbọdọ̀ ní - BBC News Yorùbá (1)

Oríṣun àwòrán, Getty

Lẹyin oṣu kan ti Aarẹ Bola Tinubu kede pe ijọba oun ti gbẹsẹ kuro lori owo ori awọn ounjẹ to n ti ilẹ okeere wọ Naijiria, ajọ Aṣọbode ilẹ wa (NCS), ti fi awọn ilana to de anfaani naa sita.

Ibẹrẹ oṣu keje ọdun 2024 ni ijọba kede anfaani naa gẹgẹ bi ọna kan lati mu idẹra ba araalu pẹlu bi ounjẹ ṣe wọn gogo.

Ṣugbọn ọsẹ kẹta lẹyin ikede Aarẹ, awọn olokoowo nla-nla ti wọn n ta ounjẹ, ṣalaye fun BBC pe awọn ṣi n sanwo ori ti ijọba kede pe oun ti mu kuro.

Alukoro ajọ Aṣọbode ilẹ Naijiria, Abdullahi Maiwada,fi atẹjade kan sita lọjọ kẹrinla oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, nibi to ti ṣalaye awọn ohun ti awọn to n ko ounjẹ wọlu gbọdọ ṣe ki wọn too le jẹ anfaani naa.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe wi, igbesẹ ijọba yii ti bẹrẹ lati ọjọ kẹẹẹdogun oṣu keje ọdun 2024, yoo si maa ṣiṣẹ lọ titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila ọdun 2024.

Ẹ o ranti pe awọn ounjẹ ti wọn yọ owo ori sisan kuro fun naa ni, irẹsi alawọ pupa, Sorghum, jeero, agbado, wiiti ati ẹwa.

" O ṣe pataki lati mọ pe owo ori ounjẹ ti ijọba yọ kuro yii ko ni i lọ titi, ki idẹrun le ba araalu pẹlu bi gbogbo rẹ ṣe wọn lasiko yii ni. Ko ni i ṣe akoba fun eto to ti wa nilẹ tipẹ fun awọn agbẹ" Maiwada lo sọ bẹẹ.

  • Àwọn obìnrin ṣe ìwọ́de alẹ̀ torí dókítà obìnrin tí wọn pa lẹ́yìn tí wọn fipá bá a lòpọ̀ nílé ìwòsàn

  • Àlàyé rèé lórí irú ikú tó pa ọmọ wa Aduke Gold àti bí ìlànà ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ - Olórí ẹbí Ajayi ṣàlàyé

Eyi ni awọn ohun ti awọn to n ko ounjẹ wọle gbọdọ ṣe lati jẹ anfaani ai san owo ori ọja bi NCS ṣe la a kalẹ

*Ileeṣẹ naa gbọdọ ti fi orukọ silẹ ni Naijiria, o si gbọdọ ti ṣiṣẹ fun o kere tan, ọdun marun-un.

* Ileeṣẹ naa gbọdọ le ṣafihan owo to n wọle fun wọn lọdun, akọsilẹ idunaa-dura wọn pẹlu owo ori ti wọn ti san lati ọdun marun-un sẹyin.

Ileeṣẹ to ba fẹẹ ko irẹsi pupa, sorghum ati jeero wọle gbọdọ fi han pe oun ni ẹrọ to le já to ọgọrun-un kan lojumọ. O si kere tan, ileeṣẹ naa gbọdọ ti ṣiṣẹ fun ọdun mẹrin. Wọn si tun gbọdọ fi han pe awọn ni ilẹ to pọ lati fi da oko.

*Ileeṣẹ to ba fẹẹ ko agbado, wiiti tabi ẹwa wọle gbọdọ jẹ ileeṣẹ to n ri si ọgbin, to si ni ilẹ oko to pọ daadaa. Abi ko jẹ ileeṣẹ to n pese ounjẹ ẹranko.

Ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si iṣuna owo ni yoo maa fun ileeṣẹ Aṣọbode Naijiria ni orukọ awọn to kunju oṣuwọn ninu awọn ileeṣẹ yii, ati iye ti wọn ya sọtọ fun wọn.

*Awọn ileeṣẹ yii gbọdọ ta ida marundinlọgọrin (75%) ọja ti wọn ko wọle labẹ ofin yii,wọn si gbọdọ ta a nilana owo naa.

*Ileeṣẹ naa gbọdọ ni akọsilẹ gidi nipa okoowo wọn, ati ilana ti wọn fi n tọju ounjẹ ti wọn gba lọna aisanwo ori yii, nitori ijọba le beere rẹ nigbakugba.

*Ileeṣẹ yoowu ti ko ba tọju ohun ti ijọba n beere, yoo padanu anfaani ti ijọba pese yii, yoo si san gbogbo owo ori to yẹ lẹkun-un rẹrẹ.

*Bakan naa ni ileeṣẹ yoowu to ba ko awọn ounjẹ yii lọ si ilẹ okeere, boya ni tutu tabi ti wọn sọ ọ di oriṣii mi-in, yoo padanu anfaani yii.

  • Kókó ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà mẹ́fà tó wà nínú àbá tí ilé aṣojú-ṣòfin wọ́gilé torí ẹ̀hónú aráàlú

  • Akòròyìn Kenya, Rukia Bulle, gba àmì ẹ̀yẹ BBC Komla Dumor 2024

Èèyàn díẹ̀ ni anfaani yìí wà fún

Oniṣowo ounjẹ kan ni ipinlẹ Katsina, Nura Hamisu Jibiya, ṣalaye pe ohun ti ijọba gbe kalẹ yii ṣoro lati jẹ anfaani rẹ, o ni eeyan diẹ lo wa fun.

Bakan naa lo kọminu si iwọnba asiko ti wọn fi silẹ fun anfaani naa.

Hamisu sọ pe igbesẹ naa yoo jẹ ki ounjẹ dinwo ni Naijiria, ṣugbọn oṣu kejila ti wọn ni yoo pari yii kere lati mu ki nnkan yipada si rere.

‘’Iṣoro mi-in to tun wa ni ti ẹnu ibode Niger ati Benin, eyi ti wọn ti tipa lati ọdun to kọja, nigba ti awọn ṣọja gbajọba ni Niger, ti wọn fi ti bọda wọn pa.

Bi wọn ko ba ṣi ẹnu ibode wọn yii, wahala ni. ‘’

Hamisu lo sọ bẹẹ.

O ni oun gbọ pe o ṣee ṣe ki awọn orilẹede mejeeji naa ṣi bọda wọn, bi wọn ba ṣi i, aa jẹ pe Naijiria yoo le maa ko irẹsi wọle daadaa.

Kí ni àwọn àgbẹ̀ wi?

Ẹgbẹ awọn agbẹ ni Naijiria ti sọ pe kiko ounjẹ wọle lati oke okun ko le tan iṣoro Naijiria.

Yunusa Halidu, Akọwe apapọ fun ẹgbẹ awọn agbẹ lorilẹede yii, lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

O ni, ‘’ imoran to daa ni pe ki wọn maa ko ounjẹ wọ Naijiria, ṣugbọn ko le tan iṣoro, ko le yi ohunkohun pada, nitori dọla ni Naijiria yoo fi ra ounjẹ bi wọn ba ti kuro ni Naijiria.

" Niṣe lo da bii pe a fẹẹ sọ orilẹede mi-in di olowo, nigba ti a n sọ ilẹ tiwa di ilẹ otoṣi”

‘Yatọ si ilẹ okeere ti igbesẹ yii fẹẹ sọ di olowo, yoo tun sọ awọn kan naa di ọlọro ni Naijiria. Emi n ṣo fun yin, igbesẹ yii ko le ṣiṣẹ, owo ọja ko ni i walẹ"

Yunusa Halidu, Akọwe apapọ fun ẹgbẹ awọn agbẹ lorilẹede yii lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

O ni ohun ti Naijiria nilo ni pe ki wọn ran iṣẹ agbẹ lọwọ, ohun to le ṣẹgun ọwọngogo ounjẹ niyẹn gẹgẹ bo ṣe sọ.

....................................................................................................................................................

Bí o bá fẹ́ẹ jẹ ànfààní àyọkúro owó orí oúnjẹ láti òkè òkun, èyíi ni àwọn ohun tí o gbọdọ̀ ní - BBC News Yorùbá (2024)

References

Top Articles
Latest Posts
Article information

Author: Horacio Brakus JD

Last Updated:

Views: 6037

Rating: 4 / 5 (51 voted)

Reviews: 82% of readers found this page helpful

Author information

Name: Horacio Brakus JD

Birthday: 1999-08-21

Address: Apt. 524 43384 Minnie Prairie, South Edda, MA 62804

Phone: +5931039998219

Job: Sales Strategist

Hobby: Sculling, Kitesurfing, Orienteering, Painting, Computer programming, Creative writing, Scuba diving

Introduction: My name is Horacio Brakus JD, I am a lively, splendid, jolly, vivacious, vast, cheerful, agreeable person who loves writing and wants to share my knowledge and understanding with you.